Won Ti Sun Igbejọ Ọga Agba NBA; Ẹgbẹ Awọn Agbẹjọro Ati Adajọ Nigeria Si Iwaju Nitori Ẹsun Ikowojẹ
Ile ẹjọ nla High Court ni ipinlẹ eko ni oni ọjọ aje ti sun igbẹjọ ati gbigbe Arẹ ẹgbe awọn agbẹjọro ati adajọ ni orilẹ ede Nigeria (Nigeria Bar Association, NBA) iyẹn ọgbẹni Paul Usoro titi da ọjọkejidinlogun oṣu ‘kejila ọdun yii.
Wọn wipe iye owo N1.4 billionu naira ni owo ti ọgbẹni Paul kojẹ.
Loni ọjọ aje ti o jẹ ọjọ ‘kẹwa osu ọdun 2018 ti a wa yii ni o yẹ ki wọn lọ mu ọgbẹni PAUL USORO sugbọn Ọgbẹni kan ti orukọ rẹ n jẹ ROTIMI OYEDEPO sọ wipe awọn ko tii fi iwe pe ẹniafurasi naa gẹgẹ bi agbẹnusọ fun ajọ EFCC ti o si bẹbẹ wipe ki ileẹjọ naa sun igbẹjọ naa siwaju ki gbogbo eto naa le lọ bi o ti yẹ ki o ri.
Ẹ KA IROYIN YII NAA: E Wo Eni Ti BABANGIDA Fe Ki Gbogbo Eniyan Dibo Fun Ni Odun 2019
Siwajusii, Oloye Wole Olanipẹkun ti o siwaju awọn agba agbẹjọro (SAN) mejila ati awọn agbẹjọro lasan ti iye wọn n lọ si bii ogun gba Ile-ẹjọ naa ni amọran wipe ki wọn fun-un ọdaran naa ni iwe naa ni ileẹjọ naa ni gbangba sugbọn bi a o ti ṣe nnkan wa yatọ si bi emi yoo ti ṣe t’emi ni ajọ EFCC fi ọrọ naa ṣe….Agbẹnusọ fun EFCC naa wipe oun ko ni ẹda iwe naa.
Adajọ ti o dari ẹjọ naa sọ wipe oun ti sun igbẹjọ naa di Ọjọkejidinlogun osu ‘kejila ọdun 2018…bẹẹni o pasẹ fun awọn EFCC ki wọn fun ẹniafura si naa ni iwe ki ọjọ naa to pe.