Skip to content

Wahala Ti Be Wo Aarin Awon Egbe PDP oooo

Wahala Ti Be Wo Aarin Awon Egbe PDP oooo

Ija ti be sile laarin egbe iselu PDP ti o mu ki awon die ninu egbe naa kuro pelu ibinnu; won si jade pelu oruko ati asia miran fun egbe tuntun ti a ko gbo oruko re ri.

Ipinya naa sele nitori eya ti won ti da sile laarin egbe PDP naa tele bi awon kan se je omo-leyin okan lara awon ti o duro fun ibo alaga egbe naa ti ko wole, ti awon miran si wa leyin awon t’oku.

pDP-Fresh-pdp-f-t-ORISUN-YORUBA-POLITICS-PDP-Elective-National-Convention-in-Abuja

Oludari egbe tuntun naa iyen Emmanuel Nwosu ti o pe oruko egbe naa ni FRESH PDPD n pe fun biba apero ti awon egbe naa se je; eyi ti won se ni December 9 ni Eagle Square ni ilu Abuja.

Gege bii ohun ti awon akoroyin gbo, adireesi egbe tuntun naa wa ni Tito Broz street, off Jimmy Carter street, Asokor. Ogbeni Nwosu so wipe nitori ibo ti won di laarin egbe naa ti ko lo  bi o ti ye ki o lo ni awon se wa ona ati gbe egbe tuntun naa duro.