Skip to content

Sisun Ni Mo Sun Omo Yin O, Oyinbo Kan Lo So Fun Ebi Shola Gaska

Sisun Ni Mo Sun Omo Yin O, Oyinbo Kan Lo So Fun Ebi Shola Gaska bee leyin ti o dana sun iyawo re.

Awon Ebi Oloogbe naa ti ke gbajari si Oko oloogbe naa lori Iku Omo won sugbon o so wipe sisun ni oun yoo sun oku omo naa. Won pariwo sii wipe awon yoo wa gbe Oku won tabi rii ki won to sin sugbon Oko re ko gba.

Idile Oloogbe na so wipe Arabinrin Shola Gaska ti o ku ni aitojo ni ile Poland iku omo awon ko gba jijo. Awon ko tii ri omo awon soju fun odun die seyin, e wa so wipe jijo lo kan. Ki won to wi, ki won to fo, Oko re ti o wa ni Ilu Poland ti fi ina Jo, ti o si je ki won rii wipe Iku ti omo awon ku kii se amuwa olorun oba.

jakub gaska

Isele yii waye lojiji ti o si fa Idagiri, ekun oun ipayinkeke bi iroyin yii ti n tan kaakakiri ori ero ayelujara.

Ninu atejade ti awon Idile Oluwashola Atunrayo Gaska ti won fe kuro lati inu idile Adefolalu so wipe Oko Oyinbo ti o fe ti oruko re nje “JAKUB (KUBA GASKA) je Eni-ibi fun igbese nlaabi ti o gbe leyin Iku omo won ti o mu ifura dani.

Iroyin Iku Oluwashola Atunrayo Gaska ti awon eniyan maa n pe ni Sholly wa bi ado oloro ti o si fo idile won si yewe-yewe ni Iroyin ti asoju Idile won Amoye Bunmi Jasmine Omeke ti o je bi aburo si Ollogbe naa. “Ni igba ti mo gbo wipe Won ti sun Egbon wa, Ori mi wu ara mi tutu leyin igba ti O ku’ Mrs Bola ‘Salt Essien-Nelson’. ti O je Egbon Oloogbe naa so pelu omije loju. Gege bi won ti so ninu atejade naa, Kosi ebi won kan kan lati Idile iya tabi Oko ni Oko naa gba laaye lati ri Oku naa tabi se eto Ikeyin fun. “Idi kan ti Oko naa fun wa ni pe Oun kan n se nnkan ti iyawo oun so pe ki oun se ti oun ba ku”

Egbon Oloogbe agba naa so wipe Oun gba ipe kan ni bii agogo mokanla aaro ni ojo kejidinlogbon wipe aburo oun ti ku o, Beeni aburo mi naa so wipe Ipe naa dun lehin igba ti awon ti soro lori ero ayelujara pelu erin ati oyaya ti oun si ba oloogbe naa soro ni Ilu Poland ni Ojo kan si Odun keresimesi. Ninu oro ti a jo so, ko si wipe ara re ko ya tabi o ni aisan kankan”. Omije si bo loju re lehin oro ti o so yii

Titi di oni oloni, “Apeere kan ti Oko buruku naa fi lele ni Iwe ti o fihan wipe Sholly ni Wahala Ninu aya re ati pe Ibi ile omo re wu” ni oro ti a ri ka ninu atejade naa.

Gege bi Oko naa Ogbeni Jakub Gaska ti so, O ni Iyawo oun dubule aisan ni ojo isegun ojokejidinlogbon odun 2016, O so wipe oun gbee lo si ile iwosan ti oun si so fun aburo oun wipe ki o maa ba oun woo titi oun yoo fi de lati ibise. Ko pe ni oun gbo Pe Iyawo oun ti gbekuru je lowo ebora laaro ojo ru ti o telee.

Egbon Oloogbe obinrin ti oruko re nje Iyaafin Essien-Nelson so wipe oun ti bere eto bi oun yoo se fi Nigeria sile lo wo Aburo oun ti o ku yii ki awon si bi awon yoo ti se eto isinku. Ninu bi oun ti se n aw awon iwe irina naa ni oun gbo wipe. Oko re so wipe oun yoo jo Oku Iyawo oun ni pe Iyaafin Essien-Nelson nikan ni yoo ri oku naa. Sugbon iyalenu ni o je nigbati arabinrin yii gbo wipe O ti Lo jo Aburo kan soso ti o ni.

Idile Shola Gaska to di oloogbe so wipe awon ti gbiyanju lati pe Ogbeni Gaska sugbon pabo ni gbogbo re jasi. Beeni akitiyan lati ba awon omo Nigeria ti o wa ni ilu Poland ati Ile asoju Nigeria ni ilu naa soro ja si pabo. Ninu Oro ti ogbeni Gaska so gbeyin, O ni “Jijo Oku naa yoo lo bi oun ti seto ko de si nnkan kan ti enikeni le se lati da oun duro”

Bi awon idile naa se bebe titi di Ojo keji Osu kinni Odun yii pe ki o ma jo oku omo won niyen sugbon Gaska ko gbo si won lenu. Kii se iyen nikan o, O tun seto isinku lati bo eeru ti o joku ni Ojo Keeje Osu Kinni odun yii lai gba ase lowo awon ebi re ti o wa ni Nigeria.

shola jakub gaska

Ebi Oloogbe Shola Gaska naa fura si gbogbo iwa ti okunrin yi wu pupo ti won si so wipe “O ye wa wipe gege bi ofin ilu Polan pe Okunrin ni o ni ase lori nnkan ti o ba je ti iyawo. ati aaye ati oku re. Sugbon o seni laanu wipe omo awon ko le so wipe ki won jo oun ti oun ba ti ku nitoripe ko ju omo odun meridinlogoji lo, bawoni o se fe ronu iku? Nnkan ti ko ye wa ni idi ti Okunrin buruku naa ko se je ki awon idile Oloogbe naa ri Omo ki o to see bo se wu.

Ninu oro won “A fe mo idi ti Jakub fi see ni kiakia lati jo aburo mi. A fe mo eri ti o daju pe Aburo wa so wipe Ki won jo oun. A si tun fe mo eri ti o daju wipe Iru Iku ti o ku looto ni o so wipe o ku.

Iwe Ile iwosan ati Eri Igba ti o fi se aisan ati beebeelo.

Shola Gaska je omo odun merindinlogun ti o lo kawe ni Ilu Poland ti o si ka Imo nipa bi a ti n kole ti awon Oloyinbo npe ni (Architecture) nibi ti o ti pade Oko re ti o fe ti won si ti fe ara won lati odun 2010.

Ebi Oloogbe wa n fi asiko yi be Ijoba Ilu Poland ati Asoju Ile wa ni Ilu poland ati Ijoba Nigeria wipe ki won be isele yii wo lati mo ofin-toto bi isele naa ti sele ati pe ki won wadi Ooto isele naa ati gbogbo nnkan ti o wa nipa Oku naa.

E Fowo sowopo pelu wa lati dekun Ipaniyan ati kede si agbaye iru isele ti o n sele si awon eniyan wa ni oke-okun.

Lori Twitter ati awon ero ayelujara miran: #JusticeForSholly ki e si Koo sibe @orisunTv