Iko Boko haram ti oga won n je Abubakar shekau ti won gbe iroyin jade nigba kan ri wipe o ti ku ni ogagun agba awon ti iha Lafiya Dole fi iwe ranni si wipe ki o jowo nnkan ija re, ki o si dawo ogun duro.
Ogagun Agba Major General Rogers Nicholas so ninu atejade ti o jade lana ojobo wipe ni ikorita ti awon de yii, ko si ona abayo fun Shekau mo ju pe ki o dawo ogun duro.
Ipe naa jade leyin Ojo bii meji ti Shekau ti so wipe ogun ti su oun ni jija.
Ogbeni Nicholas naa so wipe Iye eniyan marundinlaadowaa nni o ti ku ti egberun eniyan si jowo ara won fun awon ologun orile ede Nigeria.
Gege bi Rogers se so ni ede geesi, o wipe:
“We have crushed the heart and soul of Shekau’s group and overrun CAMP ZAIRO.
“This time around, the troops will remain in the forest and there will be no hiding place, wherever they go we will pursue them.
“He should either surrender alive or we get him,” Ko je bi o ti wi.
Nicholas tenu moo wipe awon ajagun ile wa ti yi gbogbo agbegbe ti awon omo iko boko haram sa pamo si, ti awon si duro sibe lati dekun iwa ibaje naa.
O wipe, Awon ologun ile wa ti bere ise lati so agbegbe Gwoza-Bita-Yamtake di Ilu ti awon eniyan le gbe; ti awon yio de si ojule si aginju ti o wa nibe. O wipe, awon ko ni gba awon eni-ibi Boko haram naa laaye kankan ni agbegbe naa tabi fi aye ti won maa sasi sile.
O tesiwaju lati so wipe; awon ajagun ile wa ti di gbogbo agbegbe naa ati oju popo lati fi je ki ise awon seese.
Ni ede geesi, Nicholas so wipe;
“We are geared to ensure safety on the roads so that people can travel to various parts of the state without military escort,”