Skip to content

Owo Te Baba Eni Ogofa Odun(120) To N Se Gbajue

Oloye Busari Oyewumi eni ogofa odun ni owo sikun awon agbofinro ti te pe o gba owo ti iye re to 400,000 lowo enikan ti oruko re nje Wasiu Adebisi.

Oloye Oyewunmi ni o lo koju ile ejo ti o kale silu Osogbo, arabinrin Fatima Sodamade je onidajo ni ojo aje ose ti a wa yi. 

Ecun ti won fi kan baba na ni pe, o di panpa pelu awon egbe re lati ta ile fun Adebisi sugbon ti o je ile ayederu.

Eyi ni akosile esun ti won fi kan-an lede geesi:

“That you, Chief Busari Oyewumi, and others now at large, sometime in 2015 at the back of the Powerline area, Osogbo, in the Osogbo Magisterial District, did fraudulently obtain the sum of N400,000 from one Alhaji Ganiyu Adebisi on behalf of his son, Adebisi Wasiu, on the pretext of selling a plot of land to him measuring 50 by 1000 feet, knowing that your intention was to defraud him of his money, thereby committing an offence contrary to and punishable  under Section 419 of the Criminal Code Cap 34 Vol. II Laws of Osun State of Nigeria 2003.”

Eni afurasi naa bebe pe ohun ko jebi esun ti won fi kan ohun, ti agbejoro re si ba bebe pe ki ile ejo gba itusile re ki o ma tile wa jejo.

Ile ejo naa gba ebe re pe ki o ma tile wa jejo sugbon o gbodo ni oni duro ti oyaranti kan. Won sun igbejo si ojo kini osu keta odun ti a wa yi.