Skip to content

Osu Mefa Ni E O Lo Ninu Ewon Fun Owo-Nina Nibi Ariya O – CBN

Osu Mefa Ni E O Lo Ninu Ewon Fun Owo-Nina Nibi Ariya O – CBN

Ile-ifowopamosi agba; Central Bank of Nigeria (CBN) ti so wipe osu mesan ni enikeni ti o ba jebi esun nina owo Naira nibi ode tabi ayeye kankan lati osu yii lo.

Gege bi eni ti o wa nidi owo se so lati enu igbakeji re Priscilla Eleje (Acting Director of the bank’s Currency Operations Department), O wipe pataki ni biba gbogbo omo Nigeria ati alejo soro lori bi won ti se n ba owo Nigeria je ati awon nnkan ti yoo tele enikeni ti pampe ofin ba gbamu.

Gege bi o ti so, O ni iye owo N50,000 ni eni ti o ba jebi esun naa yoo san tabi ki o f’oju ba ile-ejo pelu idajo ewon osu mefa tabi bi o se buru to; ki o sanwo ki o si tun s’ewon.

O wipe; lai gba ase lowo owon alase, enikeni ti o ba ta, tabi ko o na owo Naira ni ibi-kibi ni yoo f’ara gba egba lowo Ijoba Nigeria. Beeni Odun marun ni eni ti o ba se ayederu owo Nigeria nitori wipe o ye ki gbogbo wa mo wipe Owo Naira je ohun-amuyangan fun orile-ede Nigeria eyi ti o tumo si wipe: Ki a bowo fun owo naa.

Naira-nigezie-xtreme-Abuse-Naira-Go-To-Jail-CBN-Warns-Nigerians