Skip to content

Osinbajo so pe Epo Robi Ko Ni wulo mo Lai Pe

Osinbajo so pe Epo Robi Ko Ni wulo mo Lai Pe

Ni ojo keerin-din-logun January 2017, Igbakeji aare Ogbeni yemi Osinbanjo se abewo si ilu Gbaramatu ni Ipinle Delta eyi ti o je ara irinajo alaafia re si agbegbe Niger Delta.
OSINBAJO
Ni ibe, Igbakeji aare Yemi Osinbajo ti ro Nigeria lati wa nkan se si oro ilu ti ko lo dede ni kiakia ki won ma ba kabamo nigbeyin. O so wipe igba die pere lo ku fun epo robi lati je ohun oro gbogi ti o n mu owo wole fun Nigeria.
Siwaju si, o ni wipe “A lati yara bi asa ki a si se bi amoye”.

Lehin igba ti o se ipade pelu awon adari ilu Gbaramatu ni aafin Pere ti ilu Gbaramatu Oboro Gbaraun 11 Aketekpe, Osinbajo koju awon ara ilu na o si fun won wipe ojo iwju ile-ise epo robi ni Nigeria yi o doju ko opolopo wahala.
O ni wipe ta ba fi ma ri bi ogun si ogbon odun epo robi wa ko ni je iyebiye bi isin mo. Orile ede America ko ra epo robi lowo wa mo.

OSINBAJO
“Gbogbo awon ipinle Asia ti o an ra epe robi lowo wa tele ti bere sin ni wa ona abayo miran lati pese ina mana-mana fun orile-ede won. China, Japan, ti n seto oko ayokole ti o n lo ina mana-mana ti ina ti oorun n pese si ti di opo.

“Agbegbe Niger Delta je ibi ti opolopo eniyan bi egbawa(20,000) ti padaanu emi won laarin odun 1998 si 2015 yato si wipe agbegbe na ko ye ni gbigbe.
Ki ojo iwaju ilu Gbaramatu le dara, ohun meta ni a ni lati se;
1. A lati mo gbogbo ijakule ati wahala ti agbegbe Niger Delta ni si won si n doju ko.
2.A lati bere si ni ri agbegbe Niger Delta gege bi ibi ti o se pataki fun idagbasoke orile-ede wa
3.A lati bere si tun ilu na se ni awon ona pataki.

Gegebi o ti so, eyi nipe ijoba apapo, ijoba ipinle, ile igbimo asofin agba, ajo ti o n ri si eto epo robi ni Nigeria NDDC pelu awon osise ijoba ti o n soju Niger Delta gbodose ipade pataki papo lati wa nkan se si oro Niger Delta ki iyato to gbeye le deba agbegbe na.

Ko gbodo si awiso kankan fun won lati ma le joko jomitoro oro lori Niger Delta. Nitori ijoba apapo ko le da nikan tun Niger Delta se lai se pe ipinle na setan lati fi opo laarin owo ipinle na sile fun ise na.

Siwaju si, Igbakeji aare Osinbajo so wipe eto ilu papa julo awon ohun amuye ilu lo je ijoba apapo loogun, o si so fun won pe “Ni odun yi 2017, won ma bere ise lori reluwee lati ipinle Eko si Calabar yi ti yi o gba Niger Delta koja”.

Ni akotan, o so wipe PANDEF ti fun ijoba apapo ni ohun meerindinlogun gbogi i o ye ni gbigbe yewo eyi ti o ma se iranwo fun won lati le mo ohun ti o a tunbo mu idagbasoke wa Niger Delta.