Skip to content

#OrisunTV: Ẹ Ma Bẹru Gbogbo Ọrọ Ti NNAMDI KANU Ṣọ O – BUHARI

#OrisunTV: Ẹ Ma Bẹru Gbogbo Ọrọ Ti NNAMDI KANU Ṣọ O – BUHARI

Ijọba Orilẹ ede Nigeria ti dahun si ọrọ ti Ọgbẹni Nnamdi Kanu ti o jẹ olori awọn ijọba Biafra. Bi a ti gbọ, Buhari daa lohun wipe Orilẹ ede Nigeria labẹ akoso Muhammadu Buhari ni agbara lati bori gbogbo ọfa ti awọn eni ibi ba ta si orilẹ ede naa. Wipe ko si ewu tabi ifoya fun ẹnikan kan ni orilẹ ede naa.

Ijọba Nigeria fi ọkan awọn ọmọ Nigeria ba’lẹ wipe ki wọn ma bẹru gbogbo nnkan ti Nnamdi Kanu sọ ni igboro ẹnu rẹ.

Ni ede gẹẹsi, ọrọ naa jade wipe:

Kaka ki a maa wo gbogbo atotonu ọgbẹni Kanu gẹgẹ bi nnkan ti o fẹ gbe oju awọn orilẹ ede miran kuro lara orilẹ ede Nigeria bẹẹni gbogbo ete naa n gb’ero lati ba ajọṣepọ Nigeria pẹlu awọn orilẹ ede miran jẹ.