Skip to content

#Orisun: Ijọba Nigeria Le Fun Oṣiṣẹ Kọọkan Ni 30 Thousand Loṣu – Shehu Sanni

#Orisun: Ijọba Nigeria Le Fun Oṣiṣẹ Kọọkan Ni 30 Thousand Loṣu – Shehu Sanni

Sinetọ kan ni orilẹ ede Nigeria ti sọ wipe ko yẹ ki ijọba Nigeria maa palantia lori iye owo ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ n sọ wipe ki o jẹ oṣuwọn ti won yoo fi maa san owo fun wọn. O wipe Orilẹ ede wa tobi ju iye N30,000 naa lọ.

Sinetọ naa ti o wa lara awọn sinetọ ẹgbẹ oṣelu APC ti o fi ẹgbẹ naa silẹ leyin ti wọn ko fun-un laaye lati pada lọ si ile igbimọ asofin.

Gẹgẹ bi o ti sọ lori ẹrọ alatagba Twitter, o wipe nnkan ti o tọ fun Ijọba apapọ lati ṣe ni ki wọn gba lati san iye owo naa fun awọn oṣiṣe ti o tumọ si wipe lojoojumọ won yoo maa gba N1,000.

Ni ede gẹẹsi o wipe:

It’s fair and just for the FG to agree to 30k as minimum wage.That means 1k per day.This country can afford more than that in reality.