Skip to content

#Orisun: FAYẸMI TI KEDE ILEEWE ỌFẸ NI IPINLẸ EKITI

#Orisun: FAYẸMI TI KEDE ILEEWE ỌFẸ NI IPINLẸ EKITI

Gomina ipinlẹ Ekiti ti polongo ẹkọ ọfẹ ni ipinlẹ ekiti loni ọjọru paapa julọ ni awọn ileewe ti ijọba ṣẹda rẹ ni ipinlẹ naa.

Agbekalẹ owo fun igbedide eto ẹkọ bẹrẹ ni ọdun 2015 ti Gomina tẹlẹri Ayọdele Fayọṣe da silẹ ti awọn ileewe alakọbẹrẹ yoo maa san iye owo ẹẹdẹgbẹta naira bẹẹni awọn ileewe girama yoo maa san ẹgbẹrun naira.

Gomina Fayẹmi sọrọ nibi ipade ita gbangba kan ni Ijọba ibilẹ Ekiti North ati South lẹyin igba ti wọn bura fun-un wọ ori oye Gomina, O wipe; oun n gb’ero lati gbọn owo sisan kuro ni awọn ileewe ti o wa ni ipinlẹ naa…Ko je bi iroyin ti a ri gba ti sọ.

Osẹ kan leyin ti Fayẹmi ti bura wọle si ipo gomina naa ni o kede idaduro sisan owo ileewe naa.

O kede lori ẹrọ alatagba Twitter wipe;

“Mo ṣẹṣẹ t’ọwọ bọ’we lati da sisan owo ileewe ni awọn ileewe alakọbẹrẹ ati girama ni ipinlẹ Ekiti. Ẹkọ jẹ nnkan pataki fun awọn ọmọ wa” Ko jẹ bi Fayẹmi ti kọ.