Skip to content

Opin Ti De Ba Ise Fayawo Ni Nigeria

Opin Ti De Ba Ise Fayawo Ni Nigeria E Ma Se Gbe Oko Wo Nigeria Mo!!!

Ijoba apapo yi o jere edegberin milionu dola ninu ofin ti won sese gbe kale pe oko ayokele kankan ko gbodo ti oke-okun wa si Nigeria lai se pe o gba ori omi koja.
Iye ni ajo Nigeria Automotive Manufacturers Association (NAMA) fi se ifihan ni ojo Isegun January 17 odun 2017.

Agbenuso ati oludari ajo NAMA na Ogbeni Remi Olaofe, so wipe gbigbe moto boginni ati oko ayokele wo orile-ede Nigeria lati ori ile ti fa opolopo siso owo nu fun ijoba apapo.
“Awon orile-ede ti o wa ni egbegbe wa ni o n jere gbogbo owo ti o ye ki a ma jere lati ibi gbigbe oko ayokele wole”, Olaofe

FAYAWO

“Pelu ofin tuntun ti ijoba sese gbe kale yi, ti won ba tele daradara, owo to peye ma ma wole sinu apo ijoba. Awon ti o tin ta oko ayokole mo iru ipo ti ilu wa ki won to ma dawo le gbigbe oko wole ati oke-okun tabi awon orile-ede to wa lagbegbe wa.

Ibaje lo ti de ba orile-ede wa latari aisedede awon ti o n gbe oko ayokele wole ko se fenuso.
Ijoba apapo ko ni ki won ma gbe oko wole rara mo oooo, Won kan fe se eto to peye ki owo awon Fayawo ti ko fe jawo le segi, ki won jawo ninu iwa buruku gbigbe moto wo orile-ede wa lati inu igbo nitori pe won ko fe san owo ti o ye ti won si n gbe owo ile lo si ita ti awon ti ko ye si n je anfaani ohun ti ko to si won.

“O se paptaki ki a fi to awon eniyan leti nipa ofin tuntun yi si a si salaye bi gbogbo re se ma ma lo ni isin”.
Awon alakoso eto tuntun ni ; Distributors Scheme, Auto Finance Scheme pelu oja tuntun ti ijoba ma si fun awon ti o n ta moto tokunbo ati moto ti ki i se tuntun.

Ohun gidi to tun ma ti be jade nipe, ofin yi ma pese opolopo ise tuntun fun awon ti ko ni bi ona egberun merin (4000)pelu ise ti o ma mu owo gidi wole fun awon ti ko kawe sugbon ti won fe sise.
Ni akotan,Ogbeni Olaofe so wipe owo ti o wole lati ibi gbigbe oko ayokele lati ori ona le ni Bilionu lona meji dola($2Billion) ti o si je pe won ko fi si apo ijoba.