Skip to content

Omo Chibok Miran Ni Awon Ologun Ile Wa Tun Ti Gba Pada

Omo chibok miran ni a tun ti gbo wipe won ri gba lowo awon omo ogun Iko Boko Haram pelu omo kekere ti o bi.

Awon Omo ogun Ile Nigeria ti fi idi re mule pe won ti ri omo Chibok miran ti won gbe lojo kinni ana.

Gege bi ati gbo lenu aimoye eniyan, awon Omo ogun wa ri omo naa ni inu igbo Alargano ni ilu Borno nigbati awon omo ogun ti Lafiya Dole gba ibe koja.

Siwaju sii, Oga awon Alukoro fun Awon Ologun Ile wa, Ogagun Sani Usman so wipe awon yoo gbe iroyin miran to ba jeyo jade laipe.

Ninu Oro re, o wipe “Awon Omo ogun wa ti ri omo ileewe chibok miran. A o gbe Iroyin Lekunrere jade laipe,”  Beeni o tun wipe “Awon omo ogun ti eka Lafiya Dole nigbati won n se iwadi fura pe awon omo Iko Boko Haram fi okan lara awon omo chibok naa pamo ti oruko re si n je Rakiya Abubakar pelu omo owo ti ko tii ju osu mefa lo.chibok