Skip to content

Awon Olopa Ko Je Ki Dino Melaye Pada Sile Leyin Ti Won Ti Duro Fun-un Nile Ejo

Awon Olopa Ko Je Ki Dino Melaye Pada Sile Leyin Ti Won Ti Duro Fun-un Nile Ejo

Ojo kan leyin ti Ogbeni DIno Melaye ti f’oju ba Ile-Ejo ni agbegbe Wuse II ni ogba Onidajo agba ni Ilu Abuja, won fun-un ni aaye at pada sile nipa beeli sugbon awon olopa ti so wipe ejo naa ko te awon lorun ti won si gbe pada lo si ipinle Kogi ti won si gbe si abe abo.

A gbo wipe eni ti o sunmo ogbeni Dino Melaye laaro yii ti o je Ojobo akoko ninu osu yii so wipe won tun ti gbe Sineto naa lo ile ejo miran ni agbegbe lokoja ni ipinle Kogi naa.

Niwon igba ti o fi wa ni ile ejo ti ilu ABuja naa, o gba idasile lori owo beeli N90Million sugbon awon olopa ko fisile, won si fi si abe ahamo ni ilu Abuja ki won to pada si Kogi.

Ogbeni Melaye gb’iyanju lati da awon agbofinro naa duro ki won ma gbee lo si ipinle Kogi sugbon epa ko b’oro mo.

Davido Ma Kabamo Pe Oun Ni Baby Mama-Eedris Abdulkareem

dino-melaye-orisun-tv

Ni bi agogo merin idaji ni awon agbofinro naa gbe lo si ipinle Kogi ti won si de ilu naa ni agogo meje aaro.

Won ko so idi ti won fi ti ogbeni Dino Melaye mole. Awon olopa tenumo wipe awon ko fi Dino melaye sile nitori wipe esun odaran ni won fi kan-an eyi ti awon adigunjale fi roo lara ati esun ipaniyan.

Ki O to de, awon okunrin firigbon ni o ti wa ni agbegbe ile-ejo naa lati fi bojuto ayika naa.