Skip to content

Ogbontarigi Kan Lara Awon Omo Egbe PDP Tun Ti Lo Si APC o

Ogbontarigi Kan Lara Awon Omo Egbe PDP Tun Ti Lo Si APC o

Ko tii ju ojo die leyin ti egbe PDP (Peoples Democratic Party) ti padanu omo-egbe kan ni ile igbimo asofin sinu egbe APC; iyen All Progressive Congress, Omo egbe miran ti fi egbe PDP sile lo si egbe APC pelu esun wipe PDP ti ilekun mo oun.

Gege bi nnkan ti Agbonayinma so lede geesi, o wipe: “The PDP has shut the door against me.”

Ogbeni Johnson Agbonayinma ti o wa lati ilu Edo je okan lara awon ti o n tele Ali Modu SHeriff ti inu egbe PDP ki egbe PDP to pari ija ati aawo ti o n be laarin won ti o ku die ki o so egbe naa di oloogbe ti o si so awon eka ti Sineto Ahmed Makarfi di eni ti Oye alaga PDP tosi. Agbonayinma, Mr Shuaibu Philip ati Raphael Igbokwe naa wa lara awon ti o ti PDP kuro lo si egbe APC.

Iroyin lori e si n tesiwaju bi a se se iwadi tiwa.