Skip to content

Idi Ti Ogbeni Gabriel Jesus Fi T’owo Bo’we Lati Duro Si MAN CITY Fun Odun Miran Sii

Idi Ti Ogbeni Gabriel Jesus Fi T’owo Bo’we Lati Duro Si MAN CITY Fun Odun Miran Sii

Agbaboolu fun iko-agbaboolu Manchester City pelu oruko Gabriel Jesus ti gba lati duro pelu awon akegbee re ni Man City fun b i odun die sii (2023).

Jesus je omo odun mokanlelogun; beeni won gbaa wole si Man City lati Ilu Brazil (palmeiras) pelu iye owo £27m ni osu kinni January 2017 ti o si gba boolu wo’nu awon ni liigi ti o koko gba. Beeni o je iye goolu metadinlogun ni idije Premier League ati Carabao Cup ni saa ti o koja.

Ipababo Abija Ni Saraki Fi PDP Se O Bi A Se Gbo Wipe O Ti Di Adari Agba Fun Egbe-Oselu PDP

O ba awon orile-ede Brazil bere awon ere boolu ti won gba titi won fi de WorldCup Quarter-finals ti won ti fi’di remi lati owo Belgium.

Orunkun ati atelese re nikan ni ailera ti o ni ni iwon igba ti o de Man City.

Ni igba ti won ba Jesus Gabriel soro, o wipe “Igbese ti o dara ju laye oun ni o gbe yen”. Beeni Adari egbe-agbaboolu Manchester City naa; ogbeni Txiki Begiristain jeri si akitiyan Gabriel ninu iko naa. O wipe; Gabriel lai si ariyanjiyan je okan lara awon ti o dara julo ninu agbaboolu-iwaju ni gbogbo agbanla-aye.