Eni Ti O Seda MMM (Mavrodi) Ti Fo Sanle Lo Irin-ajo Aremabo
Iroyin ti jade wipe Ogbeni ti o da kalo-kalo ori afefe ti awon eniyan fi n gba owo ti aye mo si MMM ti gb’ekuru je lowo ebora. Eyi tumo si pe; Arakunrin naa ti o wa lati orile ede Russia iyen Serge Mavrodi ti ku.
Gege bi a ti rii gbo, Ogbeni Mavrodi ti akaso MMM re gba iye millionu nla lowo awon ara Russia ni Odun 1990 si odun ti a wa yii ku leyin ti Arun idaduro okan gbee.
Loni ojo aje ni a gbo wipe Mavrdi ti o je omo odun mejilelogota ni o pariwo aya-lile ati aya-didun ti o si fo sanle ku leyin wakati die ti won gbee de ile-iwosan ni ale ana (25th March 2018).
MMM naa je Kalo-kalo nla ti awon eniyan t’oribo kaakakiri agba nla aye pelu itankale iroyin lori bi awon eniyan se n fi owo sinu re lori ero ayelujara. O pinnu lati da iye owo ti o ji gbe pada fun bi eniyan millionu mewa sugbon ko mu ileri re se leyin igba naa.
Ni odun 1994, Mavrodi wo inu ile-igbimo asofin gege bi okan lara awon asofin ti a pada gbo wipe o lo lati fi pa enu-ofin mo ki awon eniyan si mu enu-ate kuro lara re.
Ni ilu moscow ni igba kan ri ni odun 2007, won da ejo ebi fun-un pelu ewon odun merin abo sugbon o fi ogbon alumokoroyin fi ye ejo naa.
Beeni o si se agbekale MMM miran kaakakiri orile ede bii mefa lati fi maa gba awon eniyan. Awon orile ede bii India, China, South Africa, Zimbabwe..Beeni Nigeria naa ko gbeyin k’o to di igba ti awon ijoba ilu kookan naa dawo ibi re duro ni ilu won.
Awon eniyan miran ni ki olorun tee s’afefe rere ti awon miran si so wipe “Akutunku e lona orun”
KINI EYIN LE SO NIPA “MMM” ati MAVRODI ?