Skip to content

Nnkan Meta Ti O Ye Ki A Fi Akiyesi Si Nibi Boolu Ti Nigeria Gba Pelu Argentina

Nnkan Meta Ti O Ye Ki A Fi Akiyesi Si Nibi Boolu Ti Nigeria Gba Pelu Argentina

Awon idije meji seyin ti o waye laarin Algeria pelu Argentina ti fun wan ni eri wipe Iko Super Eagles kii se omode mo. O tun je ki a mo ipo ti awon agbaboolu kookan wa bi won ti n gbe asia ile wa lo si Russia 2018.

Orisun ti se agbeyewo ohun marun ti a ri ko leko nibi Idije fun eni ti yoo gba boolu agbaye ‘World Cup’ ti o waye laarin Nigeria ati Argentina pelu bi won ti jawe olubori nibi ifesewonse naa.

Nigeria-vs-argentina-Russia-2018-NIGEZIE-SPORT

1)

Lakoko, Daniel Akpeyi ko tii dara to. Beeni Uzoho ye ki o ni anfani lati tele won lo si Russia 2018 nitoripe Daniel Akpeyi ko tii koju osuwon. Wahala ni o da sile nibi ese akoko ti won gba ti o si faa ki won gba ami ayo kan wole. Ni’dakeji, Francis Uzoho je eni ti o dena de boolu ti Benedetto d’ori gba lowo ipari ere boolu naa.

E TUN LE KA: Agbaboolu Kenneth Omeruo De Nu Igbeyawo ko Afesona Re

2)

Leekeji, Gernot Rohr je Akonimoogba ti o lopolo; nigbati awon ti won to lati wole laarin agbaboolu Super Eagles fi formation 3-5-2 lele, opo eniyan ni enu ya. Orile ede ti o po ni ko ni lo iru eto yii lati fi gba boolu sugbon ogbeni Rohr mo nnkan ti o n se ti o fi pa eto 4-3-3 sile. O mo wipe akonimoogba Argentina; ogbeni Jorge Sampaoli yoo gbe awon agbaboolu t’opo sori oun.

Idi niyen ti o fi lo Eto 3-5-2.

Nigeria-vs-Argentina-Nigeria-vs-argentina-Russia-2018-NIGEZIE-SPORT-SUPER_EAGLES

3)

Lekeeta, Opolopo agbaboolu ti o loruko ni ko gba boolu lojo naa. Awon bii

Ogenyi Onazi, Odion Ighalo, Mikel Agu, Elderson Echiejile ati Moses Simon. Nje bi apakeji Ere boolu naa ti de ni Rohr gbe awon ti o gbe ogo Super Eagles lojo naa wole. Awon bii Tyronne Ebuechi, Ahmed Musa, Brian Idowu pelu Kenneth Omeruo.

Eyi fihan wa wipe Wura ni Iko egbe agbaboolu Super Eagles je si orile ede Nigeria bi won ti muwa lo si Idije nla naa Russia 2018.

Nigeria-vs-Argentina-Nigeria-vs-argentina-Russia-2018-NIGEZIE-SPORT-SUPER_EAGLES