Skip to content

Lodun T’O N Bo, Egbe PDP Ni Yoo Wa Ni Ipo Aare Lati Dari Ayeye Iranti Ojo Ti IJOBA-Awa’rawa (Democracy Day)

Lodun T’O N Bo, Egbe PDP Ni Yoo Wa Ni Ipo Aare Lati Dari Ayeye Iranti Ojo Ti IJOBA-Awa’rawa (Democracy Day)

Alaga egbe Oselu PDP; iyen Peoples Democratic Party (PDP) Prince Uche Secondus ti so wipe Aare Muhammadu Buhari ti se Ayeye Ominira Ijoba-awa’rawa ikeyin lori aleefa.

Ninu atejade ti a ri gba lati owo ogbeni IKE ABONYI ti o je oludamoran si ogbenu Uche so wipe awon ni awon gbe Ijoba-awa’rawa laruge ju lati igb ati o ti bere; beeni egbe oselu APC ko le se nnkan-kan lati fi fidi re mule sinsin. O wipe, ti won ko ba le egbe APC kuro, afaimo ki Ijoba-awa’rawa ti a n soro nipa re yii ma parun.

Gege bi oro ti o so ni ayajo ojo naa iyen MAY 28, Alaga egbe PDP naa so wipe, awon omo orile-ede Nigeria n duro pelu ireti lati ja egbe APC ju sile beeni lati le Aare Buhari kuro lori oye pelu ibo won.

Ni Ede geesi, oro re ka bayii wipe:

“If Democracy must survive in our country we must do away with APC and Nigerians are ready and willing to do just that because they cherish democracy as the best form of government.

“Going by their poor record of performance in the last 36 months, and the determination of Nigerians to put the country in the right footing, this is the last Democracy Day this President will mark.

“Their agenda now is to intimidate, harass and scare opponents to create a Police state with the aim of turning the country into one-party state but it must be resisted by Nigerians who passed similar road before and came out victorious.

‘’The next Democracy Day May 29, 2019, which Nigerians and indeed all lovers of democracy are anxiously looking forward to would be the smooth transition from confusion and purposeless governance to real democracy which the Peoples Democratic Party (PDP) is returning to gift to the Nation.”

Aremo Uche Secondus so wipe Ijoba-awa’rawa ti awon ti n toju lati bii odun merindinlogun ti di ohun yeye ti won ko si bowo fun gegebi o ti ye ni iwon odun meta ti won ti gba Ijoba naa.

O tesiwaju lati pe awon Ileese nla nla ati agbajowo awon agbara lati oke-okun lorisirisi si eto Idibo ti o n bo ni odun 2019 nitori wipe awon egbe oselu APC ti n gbimo alumokoroyin lati yan orile ede yii je nibi idibo t’o n bo naa.

Ki olorun ki o bawa je ki odun 2019 mu irorun ba orile ede Nigeria; Ki eni ti yoo gbe Orile ede wa de ibi-giga ki o wole (Let the best Man WIN)