Leyin Osu Kan Ti Adeotan Se Igbeyawo Ni O Ku Toyun-toyun
Arabinrin ti a n pe ni Adeotan Oresajo ni a gbo wipe o fo sanle ti o si ku leyin osu kan ti o se igbeyawo pelu oko re Tope Oresajo. Iyalenu ni o je fun wa, beeni ohun ibanuje ni wipe eniyan ku toyun-toyun.
Gege bi a ti gbo, Ogbeni Tope ti o je oko re pelu Adeotan ba ara won pade ni ipinle Ondo ti Adeotan ti lo ile-iwe Wesley University Of Science and Technology ti won si fe ara won s’ona fun bii odun mejo ki won to se igbeyawo.
Leyin Igbeyawo naa, ireti nla ni oyun Adeotan mu wa fun awon ebi re gege bii igi akose re sugbon ko duro lati bi omo naa.
O ku ojo meji ki won se ayajo-ojo ti won se igbeyawo (June 24th 2018) ni a gbo wipe O subu ti won si gbe lo si ile-iwosan sugbon ko yee. Awon dokita so wipe Eje-riru ni won so wipe o paa..Sugbon ki o to de Ile-iwosan, igbe ese ni o n ke ti o si jade kuro laye pelu oyun osu mefa.
Ki oluwa ki o f’orun kee oooo!