Skip to content

Aarun Lassa Fever Ti Pa Dokita kan Ni Kogi, ati Awon Marun-un miiran Ni Ilu Ondo

Dokita kan ti oruko re n je Idowu Ahmed ti o ko aarun lassa fever (iba-ekute) nigba ti o n se itoju omo osu meje kan, ni o ti gbemi mi bayii.

Omo naa se alaisi ni ojo Eti, ojo ti won gbe wa si ile-iwosan fun itoju. A ri i gbo pe ile-iwosan kan ti o wa ni Irrua, ni Ipinle Edo ni ibi ti omo naa ti n gba itoju ni o ti je Olorun nipe.

Titi di asiko ti Ahmed fi di alaisi, o je alamojuto ile-Iwosan Ijoba Apapo ni ilu Lokoja, nibi ti o ti ko aarun naa.

Alaga awon Agbarijopo Osise-Ilera -Nigeria Medical Association ti Ipinle Kogi, Dokita Godwin Tijani se apejuwe eni to ku naa gege bi olufarasin lenu ise.

Lassa-fever1-lassa-fever-RATS-DISEASES-AFRICA

Atejade lati owo Dokita Godwin Tijani lo bayii pe; o je edun-okan fun awon lati kede iku Dokita Idowu Ahmed Victor, eni ti o je alabojuto Ile-Iwosan FMC, ni ilu Lokoja. Ile-Iwosan ni won ni o ti ko aarun yii gege bi won se fi idi re mule ni ile-iwosan kan to wa ni Irrua. Ki Olorun te e si afefe rere. Amin.

Ni ibi isele miiran, a ri i gbo pe o kere tan awon eniyan marun-un ni won ti salaisi, nigba ti awon bii mokandinlogun miiran n gba itoju lowo ni ile-wosan fun ipadabo aarun iba-ekute naa si ipinle naa.

A ri i gbo pe awon to kagbako aarun naa ni won wa lati ipinle marun-un otooto ni ipinle naa.

Komisona fun Igborosafefe ati Ifinimole, Ogbeni Yemi Olowolabi, so o di mimo fun awon akoroyin ni ana ode yii Ojo Aje ni ilu Akure.