Skip to content

Iyawo fee fun oko re ni majele je n’Ibadan, ni ile ejo ba tu won ka

Iyawo fe fun oko re ni majele je n’Ibadan, ni ile ejo ba tu won ka.

Pelu bi igbeyawo se je ayeye idunnu to, ko jo pe inu okunrin kan to n je Adekoya Taiwo dun lojo igbeyawo e bii ojo tigbeyawo ohun fori sanpon nitori sinkin ninu e n dun, ko si le pa ayo naa mora ni kete tile-ejo tu won ka. Esun igbero ika lati seku pa ni ni baba naa ka siyawo e to n je Bolanle Adekoya lese ni kootu, o lo n leri iku soun, opo igba lobinrin naa si ti leri pe oun yoo fi majele sinu ounje foun je. Gege bi awijare e ni kootu ibile, Oja-Oba to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, lasiko igbejô ôhun lojo Eti, Fraide, ose to koja, Taiwo so pe, “Ase loooto lowe awon agba to ni obinrin bimo fun ni ko pe ko ma pa ni. Obinrin te e n wo yii ko feran mi, gbogbo ero re ni ki n ku tabi ki ise bo mo mi lowo. “Aimoye igba lo ti leri si mi pe oun maa ri i pe ise bo mo mi lowo. O ni gbogbo ohun to ba gba loun yoo fun un lati je ki won le mi kuro lenu ise. Bee naa lo ni oun yoo pa mi, sugbon oun ko ni i pa mi leekan naa, diedie loun yoo maa pa mi. O ni nise loun maa lo igo kunna lubulubu, oun yoo si da a sinu elubo lafun toun a maa ro o fun mi je diedie titi ti mo fi maa ku.

 

“Ki e le mo pe oro re ti su mi patapata, mo ti fejo e sun ni tesan olopaa to wa ni Odo-Ona, nigba ti mo ri i pe awon olopaa ibe yen ko gbe igbese kiakia, mo tun loo fi sun oga olopaa ni Iyaganku, mo ni ki won ba mi gbe e ti mole ko too di pe yoo mu ileri e se, nitori to n leri pe oun yoo pa mi.” Bolanle so pe oun paapaa faramo kile-ejo tu igbeyawo oun pelu Taiwo ka nitori onijangbon eeyan kan bayii ni, o ni igba ti ifooro to n fun oun po ju loun se loo renti ile sita fawon omo meji to dagba ju ninu omo meta tawon bi. Gege bo se so, “Emi gan-an fe kile-ejo tu wa ka, sugbon mo fe ki won fun mi losu meji pere ki n too jade ninu ile e, ki n le raaye se awon eto to ba ye ki n se.” Sugbon olupejo toun pelu iyawo e n gbe iwaju ileewe ‘Baptist Grammar School’, Apata, n’Ibadan, ro ile-ejo lati ma se fi oro naa fale rara. O ni oun fe ki won fopin sibasepo naa ni kiakia nitori ojoojumo ni aya oun n ja, ati pe pelu iberubojo loun fi n ba obinrin naa gbe inu ile. Sa, Oloye Odunade Ademola ti i se adajo kootu naa ti tu igbeyawo olodun mokandinlogbon naa ka, o ni iwadii ile-ejo ti fi han pe ko si ife laarin awon mejeeji mo. O pase fun olujejo lati ko jade nile olupejo, bee lo pase fokunrin naa lati fun iyawo reô atijo yii lowo ti yoo fi gba ile oôdun kan, ko si fi egberun meta naira tobinrin naa yoo fi keru re jade le e. Si iyalenu gbogbo ero iworan ni kootu, bi Taiwo se gbo idajo yii lo ti be gija sita, nigba ti igbimo awon adajo kootu naa yoo si fi pari awon igbejo to wa niwaju won lojo naa, jagunlabi ti de, o ni owo moto tiyawo oun atijo naa yoo fi ko awon eru re jade nile oun loun yara loo gba ni banki yen. Pelu idunnu lo si fi kowo naa sile lati fi bi inu re se dun si idajo ohun han.