Skip to content

Ipababo Abija Ni Saraki Fi PDP Se O Bi A Se Gbo Wipe O Ti Di Adari Agba Fun Egbe-Oselu PDP

Ipababo Abija Ni Saraki Fi PDP Se O Bi A Se Gbo Wipe O Ti Di Alaga Agba Fun Egbe-Oselu PDP

Gegebi a ti rii gba lowuro yii, Leyin ipade laarin awon egbe-oselu PDP, Aare fun gbogbo omo ile-igbimo Asofin, Bukola Saraki ni a gbo wipe o won ti yan-an gege bi adari fun gbogbo egbe PDP ni orile ede Nigeria.

Pelu ipo nla yii ti Bukola Saraki gba ninu egbe PDP yii, Sineto Ike Ekwerenmadu ti o wa ni ipo naa teleri yoo sun fun-un kuro lori oye.

Bi Saraki se de ni awon eniyan pariwo pelu ijo ati oyaya lati pade re ti won si mu wo ibi ti won ti n se ipade pelu Alaga PDP ni gbogbo Nigeria; iyen Prince Uche Secondus ati awon agbaagba ninu egbe naa.

Ati Bukola Saraki, Ogbeni Rabiu Kwankwaso, Gomina ipinle Sokoto; iyen Aminu Tambuwal pelu Gomina ipinle Benue; Samuel Ortom ni wo wa ninu ipade naa. Ipade NEC naa ko yo awon afobaje kookan, Gomina, asoju-sofin ati awon ti o fe dije fun ipo Aare orile ede.