Skip to content

Ile Ejo Gba Nkan Ini To To $16.4m Lowo Diezani

Ile Ejo Agba ni ilu eko ti pase ki won gba nkan ini to to $16,441,906 ti o je ti minister fun epo robi (petroleun) teleri, Diezani Alison-Madueke.

Egbe Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ti gbe iwe ase na lo si odo Justice Abdulaziz Anka, ti won si fi idi e mule pe awon dukia wonyi le je ere iwa ajebanu. Eyi ko ni igba akoko ti ijoba ma gbese le nkan ini tabi owo minister tele ri yi.

E TUN LE KA: Enyeama Ma Pada Si Super Eagles- Gernot Rohr

Ni ojoru, Wednesday, August 9, 2017, Justice Chuka Obiozor ti ile ejo agba na ti pase pe ki won gbese le N7,646,700,000 ti won ri wipe o le je ti Alison-Madueke. Ase yi wa ni ojo die leyin ti ile ejo agba ni eko gbese leile ti o to $37.5m ni Banana Island patapata  ni ojo Aje Monday, August 7.

Leyin ile yi, Ile ejo naa tun pase pe ki won gbese le oye owo $2,740,197.96 and N84,537,840.70 ti won gba lati yiya ile na gbe. Ni ojo Isegun, Tuesday August 8, ajo EFCC se afihan pe awon ri  apoti ohun isaraleso bi gold, silver and diamond lati ile minister na ni Abuja.