Skip to content

Ijamba Ina Ti Be Sile Ni Agbegbe Magodo Ni Ilu EKO O

Ijamba Ina Ti Be Sile Ni Agbegbe Magodo Ni Ilu EKO O

Gbogbo wa ni a mo wipe ninu erun, ijamba ina kii pe be sile; nitoripe ogbe ti ba ile, gbogbo nnkan si ti n gbe. Eyi ni o bi iroyin ti o jade loni ni agbegbe Magodo ti ilu eko loni.

Ina naa be sile leyin ti Ileepo kan ti gba ina loni ojo aje January 15 odun 2018 nitori irin meji ti o kan ara won lara oko kan ti o n gba egbe ileepo naa koja.

Nigbati Oga agba fun ipe-pajawiri ni ilu Eko iyen LASEMA (Lagos State Emergency Management Agency) ba awon oniroyin soro, ogbeni Tiamiyu wipe

“Isele naa ti wa ni Ikawo wa, a si n gbiyanju lati je ki gbogbo eefi naa role, leyin naa ni a o ko oro lori nnkan ti o fa isele naa ti a o si mu lo si odo Ijoba fun Ojutu”.

O tesiwaju wipe Awon yoo ti ileepo naa fun ayewo; beeni won ko fi awon ti o f’arapa ninu ijamba na han titi iwadi naa yio fi pari.

Gege bi nnkan ti o n so nibi isele naa, Adari awon ajo pana-pana Lagos State Fire Service iyen ogbeni Razak Fadipe so wipe Ileepo naa gbana lati enu salensa oko ti o n koja loju popo.

Ki won to fi awon ti o f’arapa han, iroyin ti a ri gba so wipe bii iye eniyan mewa ni o ku nibi Ijamba naa ti awon miran si f’arapa.

Ki Olorun gba wa lowo awon Ijamba buruku o.

Lagos-fire-magodo-FRSC-INA-IJAMBA