IDi TI Ko Se Si Ise Fun Awon Omo Nigeria Ni CHINA Mo o – Orile Ede CHINA
Ogbeni Wale Oloko ti o je Asoju orile ede Nigeria ni ilu China ni ipinle Guangzhou ni ojoru ti o je ayajo ololufe fi oro ranse si awon odo ile wa ti o wu lati rin irin-ajo lo si orile ede Chine fun ise wipe; ki won ya’a wase si ilu miran.
Oloko so fun awon oniroyin wipe ise ni ilu china je ‘Ijoba Orun’ ti a o fi agbarakaka wo; paapajulo fun awon ti ko ni ise owo kankan laari awon omo orile ede china.
Gege bi a ti gba iroyin naa, Oloko so wipe awon ti o yanranti ninu ise owo won nikan ni orile ede china le gba nitori ileese ni o po ju ni Ilu naa. Beeni o n je ki o ye wa wipe, iye billionu 1.4 ni awon eniyan ti Ijoba ka wipe o n gbe ni Ilu china bayii ti ijoba si gbodo wa ise fun won.
Ni Ede geesi, o wipe:
“And besides, there is the language barrier for Nigerians wanting to get employment in China to contend with. “Let me therefore say that there are not much employment opportunities for Nigerians or other foreigners who want to travel to any part of China to do menial jobs,’’ Ko je bi Ogbeni Oloko Se so.
Oloko so wipe, wiwa oun pada si Nigeria wa fun ifowosowopo t’o dan monran laarin Orile-ede Nigeria ati Orile Ede china. O wipe, awon ti o ni anfani lati gbe orile ede China ni awon akeko, awon ti o wa gbafe ati awon ti o wa se kata-kara. O ni iye awon eniyan ti o wa si orile ede naa ni odun 2016 wa fun Eto eko,Ilera-ara ati lati wa se owo.
O tesiwaju wipe, ti ajosepo Orile ede Nigeria ati China ba dan daadaa…Aye yio gba awon omo wa lati le lo se ise ni ilu naa.