Skip to content

Idi Ti Goodluck Jonathan Fi So Wipe Ti Ko Ba Si Ti Saraki, Ile-Asofin Yoo Ti Daru

Idi Ti Goodluck Jonathan Fi So Wipe Ti Ko Ba Si Ti Saraki, Ile-Asofin Yoo Ti Daru

Aare Orile ede Nigeria tele ri; Ogbeni Goodluck Ebele Jonathan ni ojoru ti o koja (August 29th) ni o gbe osuba-kare fun Aare Ile igbimo-asofin agba iyen Dokita Bukola Saraki fun ise takun-takun ti o ti gbe ori alefa se gege bi olori.

Saraki se abewo si Goodluck Jonathan ni yara igbalejo re ni agbegbe Maitama ni Ilu Abuja gege bi a ti rii gbo lati enu iwe-iroyin Premium Times. Orisun rii gbo wipe Aare teleri naa atileyin nla ni Saraki ri gba lati owo awon igbimo-asofin t’oku ni gbogbo ile ti won ti n s’ofin ni Orile ede Nigeria ti gbogbo won si jeri si apere rere ti Saraki ti fi le le.

Gege bi ohun ti a ri gbo lati enu Aare teleri naa; Goodluck Jonathan ni ede geesi, O wipe:

Aare Sineeti, Je ki n fi asiko yii gb’oriyin fun e fun emi-idari ti o ni. Ti a ba n wo nnkan ti o n sele ni orile ede Nigeria, ti kii ba se opolo oludari ti o ni, Ile-igbimo Asofin agba ko ba ti wa ni juujuu, wipe didaru Ile naa tumo si pe Ijoba-awa’rawa ti sonu niyen.

Inu mi dun gidi gaan ni fun irepo ati ibasepo ti o wa laarin Ile-igbimo Asofin ati ti Asoju-sofin, paapajulo bi o se ka’pa awon igbimo naa nitori wipe isele ti o sele ti won fi gbe Asia/opa ase kuro ati idaru-dapo ko ba ti da orile ede ru sugbon o fi ogbon to gbogbo re.

Nnkan ti a ri gbo ni wipe idamu wa fun awon Ile-igbimo asofin sugbon awon Ile igbimo asoju-sofin ko daa yin da isoro naa, ti won ko ba si fi’nu tan yin, won ko ni gbe igbese naa lati duro ti yin lojo t’ogun le.

Saraki-jonathan-bukola-goodluck

Iru ise yii fihan wipe awon asoju-sofin naa gbagbo ninu ijoba re.

Ni Ede geesi:

“Senate president, let me use this opportunity to commend your leadership abilities. Looking at what is happening in the country, if not for your strong leadership, probably the National Assembly would have been in chaos and if the National Assembly is in tatters, then, of course, democracy is gone.

“I am quite pleased with the kind of relationship you have with the House of Representatives members and how you have been able to hold the National Assembly together because on the day that the parliament was invaded, though the target was the Senate, the House of Representatives members were as active as, if not more active, than the senators; and that cannot happen by chance.

“What we know is that if there is an assault on the Senate, then it is also seen as an assault on the House of Representatives. If they (House of Representatives members) don’t believe in you, I don’t think some of them would have taken that kind of risk.

Gege bi a ti rii ka lati inu iwe ti agbenuso fun Saraki lori oro iroyin ko, Sanni Onogu so wipe ipade Jonathan ati Saraki waye fun Saraki lati ki Jonathan gege bi ami iteriba beeni lati so fun-un wipe oun ti pada sinu egbe asia PDP (peoples Democratic Party). O wipe gbogbo awon eniyan ni o kan lati gbe Orile ede pada lo si ibi idagbasoke, Iwontunwonsi, idajo ododo ati ejo ti o to paapajulo lori awon isele ti o n sele ni enu ojo meta yii.