Skip to content

Eyin Obinrin E Jade Lati Se Iselu O, Ki Awon Okunrin Ma Ro Yin Seyin – AISHA BUHARI

Eyin Obinrin E Jade Lati Se Iselu O, Ki Awon Okunrin Ma Ro Yin Seyin – AISHA BUHARI

Aya Aare orile ede yii, Eni-owo Aisha Buhari ti so ni ojoru osu kejo ti a wa yii pelu ipe fun awon obinrin lati dije fun awon ipo pataki ni orile ede Nigeria lati fi gbe awon obinrin laruge fun igba pipe.

Ajo NAN (News Agency of Nigeria) s wipe Aya Aare so oro naa ni igba ti awon agbaagba obinrin labe asia APC pe jo pade lati fi atileyin won han; eyi ti o waye ni Ile Aare ni ilu Abuja.

Awon obinrin naa ti Nkechi Okorocha je oludari fun labe asia egbe APC ni ipinle marun ti o wa ni iha Guusu legbe iwo-oorun ni o n gbe leyin Mohammadu Buhari nibi ibo ti yoo waye ni odun 2019.

O wipe, Obinrin ni o po ju laarin awon ti o maa n dibo lodun-ibo ni orile-ede Nigeria eyi ti o pe fun fifi won si aarin ni igba ti o ba ti di oro fifi ipinnu lele.

Gege bi o ti so, ffifi obinrin si awon ipo nla yoo mu ki won le jiroro lori awon nnkan ti o sele si awon eniyan paapajulo bi o se kan iku iya ati omo ni orile ede Nigeria beeni fifagbara fun awon eniyan.

apc-Aisha-Buhari-orisun-tv-orisuntv

Bi Buhari se pe fun idogba laarin okunrin ati obinrin ni orile ede Nigeria lati fi dogba gbogbo ise awon egbe oselu, O ro awon agbaagba lati bowo fun ofin ati ilana egbe naa beeni ki won si gbe osuba fun eni ti o ye laarin egbe naa lati le oju-isaaju kuro ni awujo wa.

Aya aare Aisha Buhari pe fun isokan ati owo laarin awon obinrin egbe naa nitori wipe ojo iwaju awon obinrin orile ede Nigeria dara pupo.

Siwaju sii, Alaga ipade naa so wipe, idi ti awon fi pe ijoko naa ni lati ki aya Aare Aisha Buhari ti won fun ni ami-eye bi Yunifasiti Sun Moon ni orile ede South-Korea. Okorocha so wipe egbe naa kundun ijoba Buhari gidi gaan nitori wipe olori ti o see fi se awokose ni Buhari je paapajulo pelu ohun ribi-ribi ti o se si iha ti egbe naa ti wa. O fi owo so’ya wipe oun yoo gbaruku ti Buhari titi de ibi ibo lodun 2019 fun igbedide awon omo Nigeria ati itesiwaju/idagbasoke orile ede Nigeria.

Oludari fun egbe naa, Juliet Ibekaku-Nwagwu ti o gba enu awon obinrin naa soro wipe bii iye milionu marun obinrin ni o wa ni ipinle Abia, Anambra, Enugu, Ebonyi pelu ipinle Imo ti won si n fi idaniloju han wipe awon yoo duro ti Aare Mohammadu Buhari nitori wipe oun nikan ni o gba orile ede Nigeria lowo osi, are, iwa jegudujera ati ogun k’onileOgbele.

Awon ti o wa ni ibi ipade naa ni oluranlowo agba fun Aare Buhari, Hajo Sani, Igbakeji Gomina ipinle Plateau, Pauline Tallen, Alaga gbogboogbo fun egbe APC ati awon miran.