Skip to content

Kosi Eni Ti O Le Bami Soo…Eyin Buhari Ni Maa Wa – Abdullahi Adamu

Sineto fun iha iwo-oorun ni ipinle Nasarawa ni ile-igbimo Asofin agba; Senator Abdullahi Adamu ti pariwo sita wipe ko si eni ti o le ba oun so si idakeji nipa atileyin ti oun n fun Are Muhammadu Buhari ati ijoba re.

Lose ti o koja lo ni won yo Senator Adamu kuro lori aga Alaga Awon Sineto Apa Arewa iyen Northern Senators’ Forum. Beeni ninu ipade ti o waye laarin awon agbaagba egbe APC ni ipinle Nasarawa.

Gege bi idi ti won fi yo Oloye Adamu kuro lori ipo Alaga ti o wa tele ni wipe won fi esun kan-an lori iye owo N70Millionu naira ti egbe awon sineto ti iwo-oorun naa ti kojo tele ti Senator Aliyu Wamakko si ropo re gege bii Alaga egbe naa.

Nigbati won dibo lati yoo kuro lori oye ni o ti f’esi wipe oun yoo maa duro lori Ododo fun egbe Oselu APC ati Ijoba Buhari. Ko gbeyin nibe o; o se ileri wipe oun yoo sa asala fun idagbasoke ati igbayegbadun gbogbo omo Nigeria.

monkey-Buhari-with-Senator-Abdullahi-from-Nasarawa-state-

Ki gbogbo rudu-rudu ati ibo naa to sele ni gbogbo awon agbaagba egbe APC ti fowo si yiyan Adamu si ipo alaga ti Adamu je beeni won gbe osuba kare fun-un nigba ti o wa lori oye.

Nibi Ipade Oun ati awon agbaagba naa ni Ojo Aje ni o ti fi lele wipe Oun wa leyin Buhari bii Ike leyin alabahun ti awon egbe APC si wo wipe awon ri ise takun-takun ti o ti se ninu egbe naa ati ni ile-igbimo Asofin; won si jumo di ibo-idaniloju. Alhaji Ibrahim Abdullahi ni o se agbekale ibo naa ti Rep. Mohammed Ibrahim si fenu sii ninu ipade naa.

Ibrahim Abdullahi sofun awa oniroyin wipe ipade naa ni o jeki awon le wadi ohun ribi-ribi ti Adamu ti se ni bii odun mefa ti o ti lo ni Ile-igbimo Asofin.

 

Ni ede geesi o wipe;

“We the lawmakers, both at the federal and state levels, under APC from Nasarawa West including the state party executives led by the Chairman, Mr Philip Shekwo, and critical stakeholders are here to discuss on some vital national issues that affect our party and the present administration in general.

“We are loyal and in total support of what our distinguished Sen. Abduallhi Adamu is doing in defence of truth, in defence of our party and in defence of the administration of President Muhammadu Buhari, and we urged him to stand firm on that.

“We told him to continue to stand firm in defence of truth and we are solidly behind him and President Buhari beyond 2019,” he said.

 

Leyin ti won ti yo Adamu, Senator Shehu Sani so wipe iye owo ti o sonu naa le ti ba apo Obo (Monkey) ti o wo ini oko (Farm) sineto naa.

monkey-monkey-Buhari-with-Senator-Abdullahi-from-Nasarawa-state-