Gbaju-Gbaja gbomo-gbomo, Chukwudumeme Onwuamadike, ti gbogbo eniyan mo si Evans, bebe wipe ohun j’ebi esun ote ati gbomo-gbomo. O si ti lo ba oju ile-ejo giga ti Ikeja ni ilu Eko ni owuro yii. Ohun ati awon marun miran ni won fi esun ote ati gbomo-gbomo kan.
E TUN LE KA: Ile Ejo Gba Nkan Ini To To $16.4m Lowo Diezani
Adajo naa si pase wipe ki gbogbo awon okunrin ti a fi esun kan ki won si wa ni kirikiri nigbati awon obinrin ti won so wipe awon ko jebi esun ti a fi kan won, ki won wa ni kirikiri ti obinrin.
Won si sun ejo naa si ojo kokandinlogun osu kewa.