Emo Re! Awon Alarun-opolopo Fon Sita.
Awon Dokita ati Noosi ati afunni-ni-ogun {Phamacists} to le ni Egberun maarun lo dase sile ni ano ni orile-ede Kenya nigbati gbogbo akitiyan won lati je ki ijoba fi kun owo osu won jasi pabo. ni ojo aiiku (Sunday).
Awon alarun-opolo to le ni ogorun ti sa kuro ni ile iwosan alarun-opolo ni orile-ede Kenya ni ojo aje 16 January 2016 nigbati gbogbo awon Dokita ati Noosi orile-ede na da ise sile latai aifikun owo osu won.
Awon aworan ati fidio ti o jade fi awon alarun-opolo na ti won n fo iganna ile-iwosan na be si igboro ti awon kan si n gba ibe be si oju popona ni Nairobi.
Oga awon olopa agba ti orile-ede Kenya Commander Japheth Koome so wipe awon olopa ti bere ese lati sa awon alarun-opolo na kaakiri, ki won si da won pada si ile iwosan.
Siwaju si, o so wipe owo awon olopa ti ba mejila ninu awon alare na ti o sa jade nigbati awon olopa n sise. Awon Dokita na ko se daada bi won si fi ise sile ti won ko si fi enikeni so awon alare na ti won ko si fun won ni itoju to peye ki won to da ise sile.
Awon ajo na n bere fun ilewo ni ona odunrun fun awon Dokita, ati ilewo ni ona marun-le-logun si ogoji (25-40) fun awon noosi ti ijoba ti ise ileri fun won lati san ni odun 2013 sugbon ti won ko mu se ti won o de so idi ti won ko se muse.
Ogorun ninu awon ti o da ise sile na ti gbe ija lo ile eto isuwo (National Treasury) ninu awon aso ise, iboju ati fila ti won ma n wo fun ise-abe ki awon olopa to bere sin ni yin afefe oloro.
“Ko si oro, ise tabi ayiknikin kankan ti o le mi wa tabi da wa duro lati pada si ise” Eyi ni oro asoju awon Dokita, Noosi, Afunni-loogun (Pharmacists) ati Dokita eyin Samuel Oroko.
Ita gbangban ni o ti so oro yi, o si tun so fun won awon ara ilu pe ki won gberadi fun idasesile elemi gboro ti ko sele ri nitori awon Dokita ko ni pada si ise lai sepe gbogbo ohun ti won bere wa si imuse.
Awon Dokita na toka si opolopo milionu owo Kenya ti awon amofin ati asofin na danu lai si idid gidi fun ti awon Dokita to n sise takuntakun si n je ije ileri, ti ounje aro ko ba ti osan.