Ogbeni Evans ti aye n so wipe ki won da sile leyin ti won ti mu fun esun ijinigbe ati opolopo ise ibi ti o ti gbe se si wa lewon. Lana ti o je Ojo Aje, ni a rii gbo wipe Otito miran ti jade nipa Isele naa.
Chukwuemeka Okoye ti o je egbon iyawo evans ti fidi otito mule nipa ibasepo ti o wa laarin oun ati idile awon aburo re Uchenna Precious Onwuamadike ti o je iyawo Ogbontarigi Oloro Ajinigbe nni Evans. Arakunrin Chukwuemeka so wipe leyin ti aburo re ti se igbeyawo, oun ko fi ese tabi oju kan aburo oun.
E TUN LE KA:
Gege bi iroyin ti o te wa leti, Okoye so wipe, kosi ibasepo ti o dan monran laarin ebi Evans ati ebi Okoye. O so wipe titi di igbati baba awon ti fi aye sile ni odun 2014, Uchenna ti o je aburo re ati oko re ko tile yoju fun ayeye ikehin baba awon. Okoye ti o je agbe ni agbegbe Awo Oraifite ni ijoba ibile Ekwusigo ni ipinle Anambra. Beeni o tun salaye wipe, Bi o ti buru to, Awon kii soro lori ero alagbeka, beeni oun ko mo wipe aburo oun ti bi omo marun-un.
Iwadi si n tesiwaju lori Ogbeni Evans ati awon iwa buruku ti o ti se seyin. E ma gbagbe lati maa wo orisun.tv bi iroyin naa se n lo.
E LE WO FIDIO YII: