Skip to content

Egbe PDP Nikan Ni O Le Da Gbogbo Ikolo Nigeria Pada – WIKE

Gomina Nyesom Wike ti Ipinle Rivers ti so wipe orile ede wa Nigeria ti n lo si opin igbagbe, beeni egbe PDP nikan ni o le da gbogbo ikolo re pada.

Gomina naa fi esi yi sile ni Ilu Port Harcourt ni igba ti Gomina ipinle Jigawa tele ri; Alhaji Sule Lamido se abewo sii lati fi je ko mo wipe Oun fe lo fun ipo Are ni odun 2019.

Gomina wike je ki o di mimo wipe APC je ajoji ninu iselu ti won ko si ni ogbon tabi oye kankan nipa Idagbasoke Ilu. Ni ede geesi o wipe :

“If you decamp to the APC, you are no longer corrupt,  APC is a party of daylight deceit,’’

“I am happy that one of those who left to bring a messiah, has realised that the so-called messiah they brought is no longer the messiah Nigerians expect, PDP  is the only hope for Nigeria,”

Governor-Nyesom-Wike-lamido-sule

Ni Ede yoruba o tumo si wipe eni ti o ba fi egbe PDP sile lo darapo pelu APC kan jade lo sinu Iro ati etekete.

“Inu mi si dun wipe awon ti o lo gbe Olugbala wa naa ti rii wipe Olugbala iru ti e ko ni awon Omo Nigeria n wa”

O wipe, looto ni wipe egbe PDP ti se awon asise kan seyin, sugbon iyen ko da oriire ati agbara ti o wa lowo egbe naa lati fi gbe orile ede wa de ile ileri pelu gbogbo siosio ti o wa ni Orile ede naa.

Wike wipe Ipo ti Eto isuna ati iselu orile ede yii wa nilo awon oloselu ti o ni igboya lati fi gba orile ede naa.  O tesiwaju wipe, gbogbo awon ti o jere lati owo egbe PDP lati igba ti won ti da egbe naa sile naa ni won wa ni idi wahala ti o be sile ninu egbe naa. O se apejuwe Lamido gege bi eni ti o ni ife egbe naa lokan, ti o si kun oju osuwon lati koju egbe APC leyin-wa ola.

Sule-Lamido-eGovernor-Nyesom-Wike-lamido-sule

Beeni Wike ti fun ipe si gbogbo awon ti o fe lo dije fun Ibo Are lati gba ohun ti egbe ba fi lele leyin ti won ba di ibo akoko laarin egbe.

Ni igba ti Lamido soro, o wipe oun n jade lati fi ara oun sile fun odun 2019 nitori wipe Orile ede yii n fe Ilosiwaju.

Gomina teleri naa; Lamido so wipe ti won ba fun oun ni Aye ati Ase lati dari Orile ede yii, oun ni agbara lati fi ifowosowopo mule laarin gbogbo omo Nigeria, ati lati gbee sori ona ti yoo mu Itesiwaju wa.

Lamido wipe;

“Mo fe dije ni tori wipe mo mo wipe mo le see, mo ni gbogbo nnkan ti o gba, a o si ja fun ijoba-awa-ara-wa ati ipadabosipo Orile ede Nigeria”

Lamido tenu moo wipe oun yoo ba gbogbo awon agbaagba ati olori ni egbe PDP sise lati gbe orile ede yii de ibi giga.