Skip to content

E Ronu Piwada O! Okan Lara Awon Omo Iko Boko Haram Be AWon Toku

E Ronu Piwada O! Ni ede ti o jade lenu okan lara awon Omo iko Boko haram.

Loni, Die ninu awon omo iko boko haram ti o ti ronu piwada ro awon toku won wipe ki won ronu piwada ki won si gba alaafia laaye.
Okan lara awon mewa ti o jowo ara won ti oruko re n je Ogbeni Joseph David, rawo ebe si awon toku re nigbati awon Omo ogun ile wa fa awon mewa ti o ronu piwada le awon oniroyin lowo.

BOKO HARAM
Ogbeni David ti won tun mo si Ibrahim Alhaji so wipe o ro oun lorun ki oun jowo awon ohun ija ati Ado oloro ti o wa lowo re dipo alaafia.
Gege bi o ti so “Mo ti gba lati fi awon ohun ija ati ado oloro ti o wa lowo mi sile ki alaafia le joba ni ile yi. Ijoba Nigeria ti gba wa towo tese eyi ti o lodi si nkan ti awon oga wa so fun wa”
Eni a fura si miran ti o ni ki a fi oruko oun bo naa be awon toku won ti won si n fi ara pamo ni Igbo sambisa wipe ki won jowo Nnkan ija won, ki won si gba Alaafia laaye.
“Awon oga wa so fun wa wipe a ko gbodo jowo ara wa fun Ijoba Nigeria nitoripe pipa ni won o pa wa sugbon iyalenu lo je fun wa nigbati won ko se nkankan fun wa”
“Ijoba Nigeria ti gba wa towo tese, won si n se ike wa” je nnkan ti o so.
Lucky Irabo, ti o je apase Oju-ogun ti Lafiya Dole so wipe merin ninu awon Omo iko Boko haram ti o ronu piwada wa lati Ipago Mamman Nur, ti awon mefa ti o ku si wa lati Odo Shekau.
Ogbeni Irabor tun so wipe ni asiko yi, awon eniyan ti awon omo ogun Ile wa ti gba sile nigba yala yilo ni ariwa- orun le ni ẹgbẹrun ati irinwo .
Siwaju si, o so wipe awon omo iko ti o ti ronu piwada yi o faragba eto ti yo ran won lowo lati fi ipata ati jagidijagan sile ti won o si di omo ilu Nigeria rere.