Buhari ti da si rigbodiyan ti o n sele ni gusu Kaduna,o ni ki awon omo Ogun da owo ipaniyan duro.
Are Muhammed Buhari ti pase fun awon alamojuto abo ni Nigeria wipe ki won wa si ipinu lati da iwa ipaniyan ati biba dukia je ti o n sele ni gusu Kaduna
Oro na jeyo ninu ikede ti Aare orile ede fi ranse ni ojoru lati enu Malam Garba Shehu ti oje oluranlowo agba lori ero ayelujara ati gbagede fun Aare,
Shehu so wipe, nipase idari Aare Buhari, oga agba awon olopa Ibrahim Idris ti lo si gusu Kaduna ni ojo abameta ati aiku lati ri bi nkan se n lo nibe.
Siwaju si, o ni pe yato si awon olopa to ti wa ni ibe tele, won tun ti ran opolopo mopol lo si ileto naa lati rii pe abo to daju wa fun awon ara ilu naa.
Ikede naa tun fi han pe awon omo ogun Nigeria ti n se eto apapo ologun meji ni gusu Kaduna beeni awon ologun si n se amojuto gbogbo ohun ti o n lo ni agbegbe na.
Aare Buhari tun pase fun awon ti o wa ni idi ipe pajawiri bi ayara-bi-asa ti ilu Abuja lati sowo po pelu eka won to wa ni Kaduna ki won le tete pese iranlowo fun awon ti o ba se sababi rogbodiyan ti o n sele.
Lakotan, o so wipe pelu gbogbo eto ti o ti wa nile yi, o ye ki o dawo gbogbo rogbodiyan yi duro, ki alaafia si pada si ilu Kaduna.