Skip to content

Buhari Gbe Osuba-Kare Fun Gomina Ti O Wo’le Ni Ipinle Osun

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ki ọgbẹni Isiaka Oyetọla ku oriire lẹyin ti o ti gbe’gba-oroke nibi eto idibo ti o kọja lọ ni ipinlẹ ọsun.

Aarẹ Buhari ti fi ikini ranṣẹ si agọ awọn ẹgbẹ Oṣelu APC (All progressive Congress) bẹẹni o ki ọgbẹni Adegboyega Oyetọla ti o jẹ gomina tuntun ti o wọle lẹyin eto idibo ti o kọja. Buhari wipe, Idibo naa gb’omi gidi gaani.

O wipe, awọn eniyan ni ipinlẹ ọṣun ti fihan wipe inu awọn yọ si ẹgbẹ oṣelu APC bẹẹni ifọwọsowọpọ wa fun oun ni ipinlẹ naa pẹlu inu didun lori iṣelu t’o dara.

Leyin Idije naa, Aarẹ Buhari ki gbogbo awọn ti o ṣiṣẹ lati jẹ ki ẹgbẹ APC ja’we olubori nibi eto idibo naa gẹgẹ bi a ti rii ninu atẹjade ti Oluranlọwọ agba ti a ya s’ọtọ lori Iroyin ati igbohun s’afẹfẹ iyẹn Ogbẹni Garba Shehu ṣe ṣọ.

O fi iwe naa ki ọgbeni Raufu Arẹgbẹṣọla fun iṣẹ takun-takun ti o fi odindi ọdun mẹjọ ṣe ati bi o ti fi gbogbo ipa sin awọn eniyan rẹ.

Gege bi Buhari ṣe ṣọ, O wipe:

” E ṣeun oo ẹyin eniyan ipinlẹ osun fun ifọwọsowọpọ yin lati yan ijoba gomina ti o ni eto t’o dara lati inu ẹgbẹ oṣelu APC. Mo n fi daa yin loju wipe atunto ati itesiwaju oun igbesoke yoo de ba ipinle naa ati Orile ede yi ,” ..Ko jẹ bi o ti sọ.

Aarẹ Buhari pa’rọwa fun Gomina tuntun naa lati ranti ohun ti awọn oludibo n fẹ bẹẹni ki o ma gbagbe lati ṣe ohun ti o tọ lati fi mu idagbasoke ba aye awọn eniya ati awọn idile ti o wa ni ipinlẹ naa.