Skip to content

E WO Eni Ti BUHARI Gba Gegebii Agbenuso Re Fun IBO Odun 2019

E WO Eni Ti BUHARI Gba Gegebii Agbenuso Re Fun IBO Odun 2019

Iyalenu ni oro naa je ni igba ti awon omo Nigeria gbo wipe Are Buhari fe pada si ipo Are nibi ibo Odun 2019 t’onbo lona. Leyin ti o ti kede ati dije ni o se afihan eni ti yoo maa gba enu re soro ki asiko ibo naa to-to, ni igba ibo naa ati leyin ibo naa.

Buhari yan Agbejoro Festus Keyamo ti aye mo kaakakiri fun ise nla ribi-ribi ti o ti se nipa jija fun eto omo eniyan ni orile ede Nigeria.

Festus ti gba Oye Agbejoro agba (Senior Advocate of Nigeria -SAN-) ni Orile ede yii, ti o si fi Iyansipo naa han ni ori ero alatagba Social Media ti twitter wipe won ti fi oun je agbenuso Are Buhari fun odun 2019.

Gegebi O ti ko ni ede geesi:

O wipe Oun yoo soro lori re ni kikun laipe.

Gege bi a ti mo, Ki buhari to lo si iri-ajo lo si ilu Oba (UK)ni ojo kesan osu kerin, o fi Edun okan re han wipe oun fe pada lo fun ipo Are ni Nigeria lodun 2019.

Ni igba ti Archbishop of Canterbury iyen Justin Welby ni ilu London pade Buhari, o beere idi ti o fi fe pada si ipo naa….

O wipe; Leyin ti awon omo Nigeria ti pariwo lori k’oun pada tabi ki oun ma pada…Oun pinnu lati fi edun okan oun han.

Buhari-breaking-festus-keyamo-appointed-as-spokesperson-for-2019-buhari-campaign-see-appointment-letter

 

Gege bi o se so ni ede Geesi:

“We have many things to focus on, like security, agriculture, economy, anti-corruption, and many others. We needed to concentrate on them, and politics should not be a distraction. The majority of Nigerians appreciate what we are doing, and that is why I am re-contesting.”

Are tesiwaju lati so awon ohun ribi-ribi ti ijoba re ti gbe se si alejo re ni ilu london paapajulo lori eto Ogbin (Agriculture) ni Orile ede Nigeria.

O wipe:

“We have cut the importation of rice by about 90%, saving billions of dollars in the process. People who rushed into petrol money have now gone back to agriculture. Even professionals have gone back to the land. Nigeria should be able to feed itself comfortably soon. I am so pleased,” the President said.

Lori wahala awon gbemo-gbemo ati Boko_Haram, o so wipe Kiko awon eniyan leko ni nnkan ti o kan lowo yii ki won le bo lowo etan ti o wa ninu esin ati asa. O tesiwaju wipe ko si esin kankan ti o gba pipa omolakeji lekun tabi ipaniyan laaye.

Alejo re ti o je ore re Justin Welby beere lowo re nipa Ija laarin awon daran-daran ati awon agbe ni orile ede Nigeria; Buhari daa lohun wipe Wahala naa dagba ju awon eniyan lo nitori wipe, ati ibere-pepe ni o ti wa ki eran maa damu nnkan ogbin sugbon laye ode oni, nnkan ti o je ki o buru ni pe, awon darandaran ohun ngbe ibon ati awon ohun ija oloro wa lati ja, won si wa lati ilu miran ni kii se Orile ede Nigeria ni awon fulani naa ti wa…Ko je bi Are ti so.

Ko da’nu duro nibe, o wipe awon daran-daran naa je eyi ti Muammar Gadaffi ti orile ede Libya ko ni ise sugbon leyin iku Gadafi ni won ti n sakiri ti won si n se ose kiri gbogbo orile ede ti won le de. Opo ninu won ni Buhari jeki a mo wipe awon pade ni igba ti won n koju awon omo-iko Boko Haram.

Buhari ka’gba oro naa nile wipe wahala naa kiise Ija-esin sugbon wahala Adugbo ati eto isuna ni orile ede Nigeria ti awon si n sise takun-takun lati daduro laipe ti oun yoo si fi eyin awon ti o wa nidi oro naa ti agba.