Bi Buhari Se Bura Fun Awon Akapo-lailai Meje
Are Buhari ti fikun awon akapo-lailai ti o ti yan tele si ipo ni ose yii. Tele, bii meji le logun ni o yan; bakannaa ni meje ti o ku ni o fikun loni.
Eto ibura naa bere ki awon agbaagba orile ede yii to bere ipade won ti awon ti o n ba Buhari sise papo wa lori ijoko ati awon permanent secretary ti won ti yan tele; awon alejo ti o wa woran naa ko gbeyin.
Are ko ti e soro kankan leyin ibura yii, won kan bere ipade naa leyin ibura naa lesekese.
Awon ti won bura wole naa ni:
Mr Mustapha Suleiman (Kano); Mr Adekunle Adeyemi (Oyo); Mrs Comfort Ekaro (Rivers) Mr Adebayo Akpata (Ekiti).
Beeni Dr Abdulkadir Muazu(Kaduna); Mr Marcelinus Osuji(Imo) ati Mr Bitrus Nabasu (Plateau) wa lara awon ti won bura fun.
Iroyin ti o wa si etiigbo wa ni wipe, pupo ninu awon ti won bura fun ni won ti gba iwe ise tele.