Owo sikun awon Olopa ni Nassarawa tit e iyawo ile (20) ti o n je Aisha Isah nitoripe o so awon omo orogun re meji sinu konga nitori edeaiyede ti o ni pelu iya awon omo naa…
Agbenuso fun awon Olopa, DSP Kennedy Idirisu, so nibi iforowanilenuwo pe owo won te odaran naa ni abule Yelwan-Bassa ni Kokona Local Government Area leyin ti won wa fi esun naa kan arabirin naa. O so wipe arabirin naa jewo si esun ti won fi sun o si so wipe oun kabamo lroi nkan ti oun se. O tun so siwaju si wipe iwadi awon fi ye won pe Aisha ti o je iyawo keji Alhaji Isah ma n ja pelu Maimuna ti o je iyale ni gbogbo igba atiwipe gbogbo igbiyanju won lati pari ija naa pabo lo n jasi .
Agbenuso olopa so wipe aisha so wipe iyale oun ni o man ti awon omo re ppe ki won ma je ise fun oun ti o si dun oun nitoripe oun o ti bi omo nigbati omo ti o bi ni 2016 se aisi leyin osu mefa. Ogbeni Idrisun tun so wipe aisha kaa pe oun ju omo akoko Baaba sinu konga ni April sugbon ko si eni Kankan ti o ri nigba ti on se, nitorina won ro pe omo naa lo se si jabo sinu konga ti o si ku. Ni August 26, Agbenuso fun Olopa so wipe aisha ke gbanjari pe omo keji Zainab naa ti jabo sinu konga ti oko re si wo inu e lo lati gbe jade sugbon oku re lo gbe jade. Eyin eyi ni won ri wipe owo omo naa wani siso, eyi lo je ki won bere sin i fura wipe ejo lowo ninu, ti won si fura si aisha titi ti won fi faa le olopa lowo.
Gegebi Agbenuso Olopa se so, Aisha pada jewo pe oun lo’un wan i idi iku awon omo mejeeji, ti awon olopa si so wipe o ma fi oju ba ile ejo ti iwadi won ba kasenle tan…