Skip to content

AWỌN ỌMỌ NIGERIA KO LE MAA ṢE BI ẸRU NI ORILẸ EDE MIRAN TI ORILẸ EDE WA BA RI BI A TI FẸ

 

 

Ogbẹni FEMI ADEṢINA ti o jẹ oludamọran fun Arẹ orilẹ-ede Nigeria wa lori ọrọ Awon oniroyin ati ipolongo (media and publicity) ti wipe ohun pataki ti ko jẹ ki awọn ọmọ Nigeria niyi ni orilẹ ede miran ni pe Orilẹ ede ti wọn ko duro daadaa; nitori wipe ti o ba ri bi o ti yẹ ki o ri, Wọn ko ni fi wa ṣe ẹru ni awọn ilẹ ajoji.

Ni ibi eto ‘Naija Youth Talk” ti ajọ United Nations Children’s Fund iyẹn UNICEF ṣe agbekalẹ rẹ ni ilu Abuja; eyi ti o waye ni ọjọ Aje, ọjọ’kẹsan oṣun September ti a wa yii.

Gẹgẹ bi o ti wi, Awọn ọmọ Nigeria awọn ti o n pani lori ọrọ XENOPHOBIA ti o n ṣẹlẹ yii ko ni ri ọmọ Nigeria kankan pa ti wọn ko ba si ni orilẹ ede naa…bẹẹni ti ilu ba dara, kosi nnkan ti yoo le Ọmọ Nigeria kan kan lọ jiya tabi d’ojukọ iku ni orilẹ ede miran