Skip to content

Immigration Service Ti Ko Eru Awon Ajoji Bi 450 Jade Sita Kuro Ni’lu Edo

Immigration Service Ti Ko Eru Awon Ajoji Bi 450 Jade Sita Kuro Ni’lu Edo

illegal-immigrants-adamawa-immigration-orisun-tv

Immigration Service ni ilu Edo ti o maa n bojuto Wiwole ati jijade awon eniyan ni Ilu kan si omiran ni ipinle Edo ko eru awon ajoji ti ko leto lati gbe ni ilu naa jade ni saa odun ti o koja yii.

Ogagun agba awon Ajo naa, Ogbeni David Adi so bee nibi ti won ti da Oko Hilux kan pada fun Ileese Okomu Oil Palm Company PLC ni ipinle Benin.

Ogbene Adi so wipe awon ti won le pade yii je omo orilede Niger Republic ati Ghana. O tun so wipe won je awon ti ko ki n se omo ori lede yii ti won si le se akoba fun orile ede yii.

O so wipe awon odaran yii ko ni iwe irin-ajo to ye, won si n gbe ni Alaafia. Ogbeni Adi dupe lowo Okomu Oil Palm Company Plc wipe won ma n mu ise awon ya daadaa.

O wipe, Aseyori awon lori awon eniyan ti a n soro re yii ko seyin awon ileese naa ati awon ileese miran ni ipinle naa.

Siwaju sii, Awon Ileese naa ti gbe kanga-dero fun awon ni agbegbe Iguobazuwa ni iha-ariwa iwo oorun ijoba ibile ti ilu Edo.

 “Awon ileese Oil Palm Company Plc gba lati pa oko naa da fun awon Ajo Nigeria Immigration ni Ilu Edo.

Awon Ajo Nigeria Immigration dupe gidi gan lowo Oga Ile-ise naa.

Oga Ajo Nigeria Immigration ti pinnu lati je ise naa fun gbogbo Ajo Nigeria Immigration Service lapapo ati wipe, Oun ni igbagbo wipe awon ile-ise yoku won yoo gbe tele iru igbese yii.

Oludari Okomu Oil Palm Company Plc Dr Graham Heifer, so wipe igbese ti awon gbe je ohun ti ileese awon ti pinnu lati fi se idagbasoke ilu fun NIS lati fi gbe ise won laruge.

Heifer so wipe “Awon Ajo immigration ti ma n ran wa lowo nipa fifun awon ti ko ki n se omo ilu won ni eko, ki won le maa se ohun ti o to ati ohun ti o ye”. Heifer so wipe awon marundilogun lo wa lati South Africa, Kenya, ati America. Won si n se ise ni ile-ise awon.

 “won si rii daju wipe won wa sinu ilu ni ona to ye.

 ‘’Öjuse wa ni gegebii Ise asefadugbo lati ran Ajo Immigration Service lowo lori ise won.

 “Heifer wipe Ile-ise won ni igbagbo wipe oko naa ti won ti pada yoo sun bi won ti n sise siwaju.

E LE WO FIDIO YII: