Atiku Ti So Ni Gbangba Wipe Oun Fe Lo fun Ipo Are Ni Odun 2019
Igbakeji Are orile ede teleri ni aye igba Obasanjo iyen Atiku Abubakar ti bo si gbangba lati fi aniyan re han nipa ibo odun 2019 labe asia egbe Oselu PDP (Peoples Democratic Party).
Awuye-wuye ti n jade bi osu die seyin leyin igba ti o fi egbe APC sile.
O fi aniyan naa mule ni igba ti o n ba awon agbaagba egbe PDP soro lati Ijoba ibile metalelogun ni ipinle Rivers.
Gege bi Atiku se so, o fi aniyan yii han nitori akitiyan Gomina ipinle naa Nyewom Wike ti won pe ni Okun Emi egbe PDP.
O wipe, gbogbo igba ni Ogbeni Wike ma n ran oun leti nnkan ti oun duro fun ni odun 1998/99.
O tesiwaju lati so wipe, ni abe Asia egbe APC ni Eto-isuna orile ede Nigeria ti wo lule. O so wipe oun kun oju osuwon nipase ise ribiribi ti oun se ni aye igba ti oun je Igbakeji Are ni odun naa lohun.
“We all know what we have gone through in this country in the last three years.
“I can tell you throughout the whole of today that where the PDP left us in the last three years whether in the education sector, in the health sector, or in the economy, we have been going down in every statistics.“That is why I have offered myself to run for the President of the Federal Republic of Nigeria in 2019,” he said.
Gomina Wike daalogun wipe pelu ATiku, ti awon ba de ipo naa; inu awon yi o dun gidi gan ti egbe PDP ba pada gba agbara.