Alagbara Kan Tun Ti Fi APC Sile Lo Si Egbe PDP O
O dabi pe gbogbo eniyan ti n pada si egbe PDP ooo..Bi gbogbo nnkan se nlo ni ipinle Kwara, Kayeefi lo n muwa fun wa bi a se rii gba wipe iye egberin (800) omo-egbe APC ni o ti bo si egbe PDP (iyen Peoples Democratic Party).
Ogbeni Iyiola Oyedepo ti o je Alaga fun egbe PDP ni ipinle Kwara ni o gba awon omo-egbe tuntun ti o wa ni ilu Ilorin ni ojo Eti ti o koja ni igba ti Iyiola gba Alejo awon agbaagba inu egbe naa lalejo ni Ojo naa.
Dokita Hanafi Alabere ti o saaju awon ti o kuro ninu egbe naa lati agbegbe Alanamu ni ijoba ibile Ilorin-west so wipe oro ati eto ti egbe APC ni ti su awon; eyi ni o faa ti won fi lo sinu egbe PDP.
Alaga egbe PDP wayii so fun awon asoju egbe naa ti o ba ilu ilorin l’alejo wipe ‘Bi oun se ri awon omo egbe naa ko jo oun loju nitoripe egbe PDP kii se aimo fun awon ti o wa ni ipinle Kwara.
Alagba Iha ti ipinle Kwara bo si; Ogbeni Theophilus Dakas dupe lowo awon oga agba egbe PDP ni ipinle Kwara fun akitiyan won lori egbe naa lai fi ti ija ti o sele ninu egbe naa se.
O bebe wipe ki awon omo egbe naa tesiwaju lati maa se ise takun-takun fun idagbasoke egbe PDP ti o jeyo ninu pakaleke laari omo-egbe naa.
Ogbeni Dakas so wipe Inu oun dun gidi gaani fun akitiyan won lori bi awon agbegbe kookan se n se egbe naa paapajulo ipa ti won ko nibi Ibo Ijoba ibile ti ojo mejidinlogun Osu Beelu odun ti o koja; iyen 2017.
Ni afikun, o wipe igba tuntun ti awon de yii wa fun Saa oriire ati alaafia; paapajulo ifimule Ijoba-awa-arawa(Democracy)