Skip to content

Ado Oloro Miran Tun Ti Dun Ni Nigeria O

Ado Oloro tun ti dun ni Nigeria o bi a se ri awon eniyan ti wo n sa Hila-hilo kiri apa Ariwa Nigeria. Bi eni ti o fi ojuri isele na ti o pe ara re ni Baba so wipe Isele naa sele ni Ibode ti o wo ilu naa.

Awon eniyan to po ni iberu wa wipe won ti ku ni aaro ti Ado oloro naa dun ni Ijoba ibile Madagali ti ilu adamawa. Gege  bi o ti so, “A gbo ti ado oloro meta dun ni egbe Ibode ti o wo odo wa nibi ti awon eniyan duro si lati se ayewo ki won to wo inu Oja nitori pe oni ni Ojo oja.”

“Awon Apani-parae naa yin ado naa mora won pelu awon asobode meji ti o da won duro lati ma wo ilu naa.” je ohun ti BABA so.

ado oloro

Lori Isele yii, Okan lara awon asofin ile wa ti o n soju Madagali/Michika Ogbeni Adamu Kamale, so wipe oun gba iroyin isele naa sugbon iroyin ti oun gbo ni pe ko si eniyan kankan ti o ku ninu ijamba naa. “Iroyin ti won gbe wa ba mi nni pe ko si enikeni ti o so emi re nu ninu ijamba naa sugbon awon ti o fi ara pa lo poju” , Kamale lo soro bee.

O pe fun awon egbe ologun ki won wa gbogbo agbegbe naa fun awon eni ibi miran ti o ba fe gbabode fun Ilu naa.

Nigbati awon oniroyin ba Alaga Ijoba Ibile Alhaji Yusuf Mohammed, O so wipe looto ni pe Isele naa sele sugbon oun ko le fi idi nnkan ti o selegangan mule nitoripe oun ko si nle nigbati isele naa sele. Gege bi o ti so; “Mo jade fun ise pataki kan lati ibi ise sugbon won pe mi wipe isele nlaabi naa ti sele”

E TUN LE KA IROYIN MIRAN NIBI:

 

Ki Olorun Oba dawo Iji ti o n ja ile wa re o.