Skip to content

OJU TITI NI O JẸ FUN MI WIPE MI O TII RI OWO AWỌN OṢIṢẸ-FẸYINTI SAN NI IPINLẸ BENUE

 

Awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ni ipinlẹ Benue ti kọ ẹyin si aṣẹ ti Gomina ipinlẹ Benue fi le’lẹ fun wọn; ki wọn fi iwaju Ile Ijọba (Government house) silẹ ni Olu’lu ipinlẹ naa: Makurdi.

Ni ọsẹ ti o kọja ni awọn oṣiṣẹ-feyinti naa ko ara wọn jọ pọ si ẹnu ọna ọfiisi Ọgbẹni Gomina Samuel Ortom awọn ti ẹni ati bẹẹdi wipe awọn ki yoo kuro titi Gomina yoo fi gbọ ẹkun awọn.

Awọn oṣiṣẹ-fẹyinti naa wipe awọn ko tii gba ajẹmọnu awọn ati owo pension wọn fun bii ọdun meji abọ bayii.

Ẹni ti o dari iwọde naa; Ọgbẹni Peter Kyado ni o wipe inu awọn ko dun bẹẹni awọn ko tii ṣetan ati gba kamu lori ọrọ naa.

Ni igba ti a gbọ lati ẹnu Ọgbẹni Otorm, O wipe ibanujẹ ni iwa awọn Oṣiṣẹ-fẹyinti naa jẹ fun oun. O wipe lati igba ti oun ti gun ori aga aleefa oun ti san iye owo 17Billion gẹgẹ bii owo ajẹmọnu bẹẹni oun san iye owo 34 Billionu naira fun owo ifẹyinti awọn eniyan naa eyi ti o jẹ diẹ ninu owo ti ijọba ti tẹle jẹ wọn

Tags: